Mark 15:22-32

22 aWọ́n sì mú Jesu wá sí Gọlgọta, (èyí tí ìtumọ̀ rẹ̀ ń jẹ́ Ibi Agbárí) 23Wọ́n sì fi (myrri) wáìnì tí a dàpọ̀ mọ́ òjìá fún un mu, ṣùgbọ́n òun kò gbà á. 24 bWọ́n sì kàn án mọ́ àgbélébùú. Wọ́n sì pín aṣọ rẹ̀ láàrín ara wọn, wọ́n dìbò lórí àwọn aṣọ náà ni kí wọn bá à lè mọ èyí tí yóò jẹ́ ti olúkúlùkù.

25Ní wákàtí kẹta ọjọ́ ni wọ́n kàn án mọ́ àgbélébùú. 26Àkọlé ìfisùn tí wọ́n kọ sókè orí rẹ̀ ni:

ọba àwọn júù.
27Wọ́n sì kan àwọn olè méjì mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀, ọ̀kan lọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀, èkejì lọ́wọ́ òsì rẹ̀. 28Eléyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ ìwé Mímọ́ ṣẹ wí pé, “Wọ́n kà á pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn búburú.” 29 cÀwọn tí ń kọjá lọ sì ń fi ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n ń mi orí wọn pẹ̀lú, wọ́n sì ké pé, “Háà! Ìwọ tí yóò wó tẹmpili tí yóò sì tún un kọ́ láàrín ọjọ́ mẹ́ta, 30sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” 31 dBákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. 32Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.

Copyright information for YorBMYO